Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Filemoni 1:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn.

  2. Filemoni 1:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ.

  3. Filemoni 1:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ń fẹ́ arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi.

  4. Filemoni 1:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.

  5. Filemoni 1:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ó ku ohun kan, ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

  6. Filemoni 1:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Epafira, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kristi Jesu kí ọ.

  7. Filemoni 1:24nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi.

  8. Filemoni 1:25nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

  9. Heberu 1:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,

  10. Heberu 1:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.

  11. Heberu 1:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.

  12. Heberu 1:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn.

  13. Heberu 1:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ”? Àti pẹ̀lú pé, “Èmi yóò jẹ́ baba fún un, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”?

  14. Heberu 1:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”

  15. Heberu 1:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé, “Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

  16. Heberu 1:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni, ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

  17. Heberu 1:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú; nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi àmì òróró ayọ̀ yàn ọ tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

  18. Heberu 1:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.

  19. Heberu 1:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.

  20. Heberu 1:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ, bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ̀ kì yóò yípadà àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”

  21. Heberu 1:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?

  22. Heberu 1:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?

  23. Heberu 2:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan.

  24. Heberu 2:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i,

  25. Heberu 2:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnra rẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.