Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni nínú yín máa ṣe rẹ arákùnrin rẹ̀ jẹ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

  2. A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá.

  3. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀.

  4. Nítorí pé, Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde.

  5. Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé.

  6. nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru.

  7. Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi.

  8. Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀.

  9. Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa.

  10. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.

  11. Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa.

  12. Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

  13. Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.

  14. Ki oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín.

  15. Paulu, Sila àti Timotiu, Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

  16. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi Olúwa.

  17. Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára.

  18. Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìyìnrere Jesu Olúwa wa.

  19. A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀,

  20. ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.

  21. Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde.

  22. Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.

  23. Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará,

  24. kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná.

  25. Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun.