Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.

  2. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

  3. Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu,

  4. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu,

  5. kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

  6. Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.

  7. Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu,

  8. Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa.

  9. Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run,

  10. ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé,

  11. ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìyìnrere.

  12. Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

  13. Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu.

  14. Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.

  15. Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

  16. Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu.

  17. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.

  18. Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.

  19. Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.

  20. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.

  21. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.

  22. Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba. Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.

  23. Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòtítọ́, nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

  24. Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.

  25. Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúrò nínú àìṣòdodo.”