Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked

724 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.

  2. Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.

  3. Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.

  4. Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?

  5. “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀? Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.

  6. Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.

  7. Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.

  8. Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun.

  9. Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.

  10. “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.

  11. Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’

  12. Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn,

  13. pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun. A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.

  14. Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?

  15. Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.

  16. Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn. Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.

  17. Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?

  18. “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

  19. Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá, kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.

  20. Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró. Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

  21. tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀, lórí erùpẹ̀ àti wúrà Ofiri lábẹ́ òkúta odò,

  22. nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  23. Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  24. Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.

  25. Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ; ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.