- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked: Contrasted with the righteous
Àwọn ẹsẹ nípa Contrasted with the righteous
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
Olúwa ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí. Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.
Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.
nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé.
Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin; nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀; ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
Ọlọ́run gbé aláìlera kalẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
Saamu ti Asafu. Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára.
Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.