Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked: Spirit of God withdrawn from

7 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Spirit of God withdrawn from

  1. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”

  2. Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!

  3. Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán, wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè. Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.

  4. Ìjì ni yóò gbá wọn lọ. Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.

  5. Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́.

  6. Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà.

  7. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe.