Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked: False hope of
Àwọn ẹsẹ nípa False hope of
Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’