Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked

724 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.

  2. Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.

  3. Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.

  4. Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n; nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.

  5. “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.

  6. Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.

  7. Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.

  8. Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun, Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.

  9. Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.

  10. O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá. Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;

  11. òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.

  12. Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i.

  13. Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.

  14. Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

  15. Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?

  16. Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.

  17. Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.

  18. Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.

  19. Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.

  20. Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.

  21. Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.

  22. Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.

  23. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

  24. Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.

  25. “Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?