Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wicked

724 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i?

  2. “Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè.

  3. Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.

  4. Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.

  5. Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;

  6. àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó; àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.

  7. Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.

  8. Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ.

  9. Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.

  10. Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.

  11. Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

  12. Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”

  13. Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.

  14. Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn,

  15. nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,

  16. kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;

  17. Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.

  18. “A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀; pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,

  19. bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.

  20. Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.

  21. Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.

  22. Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,

  23. nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú; èmi ti rà á padà.

  24. Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;

  25. Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.