Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribes of Israel

241 ẹsẹ · 21 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa.

  2. Nígbà tí ọdún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ baba ńlá wọn.”

  3. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà.

  4. Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Selofehadi: wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.

  5. Kò sí ogún kan ní Israẹli tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Israẹli ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn pamọ́.

  6. Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Israẹli lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.

  7. Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”

  8. Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.

  9. Gbogbo ìyókù Gileadi àti gbogbo Baṣani, ní ilẹ̀ ọba Ogu ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase. (Gbogbo agbègbè Argobu ni Baṣani tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Refaimu.

  10. Jairi ọ̀kan nínú àwọn ìran Manase gba gbogbo agbègbè Argobu títí dé ààlà àwọn ará Geṣuri àti àwọn ará Maakati; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Baṣani fi ń jẹ́ Hafoti-Jairi títí di òní.)

  11. Mo sì fi Gileadi fún Makiri,

  12. ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Reubeni àti ọmọ Gadi ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gileadi lọ dé odò Arnoni (àárín odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jabbok. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ammoni.

  13. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah pẹ̀lú, àti Jordani gẹ́gẹ́ bí òpin ilẹ̀ rẹ̀, láti Kinnereti lọ títí dé Òkun pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah, àní Òkun Iyọ̀, ní ìsàlẹ̀ àwọn orísun Pisga ní ìhà ìlà-oòrùn.

  14. Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ní i. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín: ará Israẹli.

  15. Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín (mo mọ̀ pé ẹ ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀) lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín,

  16. títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jordani. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”

  17. Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini.

  18. Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

  19. “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú, tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”

  20. Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda: “Olúwa gbọ́ ohùn Juda kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá. Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un, kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”

  21. Ní ti Lefi ó wí pé, “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní Massa, ìwọ bá jà ní omi Meriba.

  22. Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, ‘Èmi kò buyì fún wọn.’ Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.

  23. Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀ àti Israẹli ní òfin rẹ̀. Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.

  24. Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa, kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i; àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

  25. Ní ti Benjamini ó wí pé, “Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́, ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”