Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribes of Israel: All inheritance to remain in the tribe and family to which allotted

7 ẹsẹ · 21 abala

Àwọn ẹsẹ nípa All inheritance to remain in the tribe and family to which allotted

  1. Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa.

  2. Nígbà tí ọdún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ baba ńlá wọn.”

  3. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà.

  4. Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Selofehadi: wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.

  5. Kò sí ogún kan ní Israẹli tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Israẹli ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn pamọ́.

  6. Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Israẹli lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.

  7. Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”