Skip to content

Mahanaim

13 verses

32.2100, 35.6300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Mahanaim

  1. Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run ni èyí!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Mahanaimu.

  2. àti láti Heṣboni lọ sí Ramati-Mispa àti Betonimu, àti láti Mahanaimu sí agbègbè ìlú Debiri,

  3. Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Mahanaimu àti gbogbo Baṣani, gbogbo agbègbè ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani, èyí tí í ṣe ibùgbé Jairi ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú,

  4. Láti ara ẹ̀yà Gadi ni wọ́n ti fún wọn ní Ramoti ní Gileadi (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Mahanaimu,

  5. Lákòókò yìí, Abneri ọmọ Neri olórí ogun Saulu ti mú Iṣboṣeti ọmọ Saulu, ó sì mú un kọjá sí Mahanaimu.

  6. Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni.

  7. Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu.

  8. Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Absalomu sì gòkè odò Jordani, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli pẹ̀lú rẹ̀.

  9. Nígbà tí Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba tí àwọn ọmọ Ammoni, àti Makiri ọmọ Ammieli ti Lo-Debari, àti Barsillai ará Gileadi ti Rogelimu.

  10. Barsillai sì jẹ́ arúgbó ọkùnrin gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni, ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Mahanaimu; nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe.

  11. “Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi Olúwa búra fún un pé, ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’

  12. Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu

  13. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,