Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribes of Israel: Settled on east side of Jordan
Àwọn ẹsẹ nípa Settled on east side of Jordan
Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.
Gbogbo ìyókù Gileadi àti gbogbo Baṣani, ní ilẹ̀ ọba Ogu ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase. (Gbogbo agbègbè Argobu ni Baṣani tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Refaimu.
Jairi ọ̀kan nínú àwọn ìran Manase gba gbogbo agbègbè Argobu títí dé ààlà àwọn ará Geṣuri àti àwọn ará Maakati; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Baṣani fi ń jẹ́ Hafoti-Jairi títí di òní.)
Mo sì fi Gileadi fún Makiri,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Reubeni àti ọmọ Gadi ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gileadi lọ dé odò Arnoni (àárín odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jabbok. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ammoni.
Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah pẹ̀lú, àti Jordani gẹ́gẹ́ bí òpin ilẹ̀ rẹ̀, láti Kinnereti lọ títí dé Òkun pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah, àní Òkun Iyọ̀, ní ìsàlẹ̀ àwọn orísun Pisga ní ìhà ìlà-oòrùn.
Ààlà àwọn ọmọ Reubeni ni etí odò Jordani. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Reubeni ní agbo ilé ní agbo ilé.
Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ẹ̀yà Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé.
Agbègbè ìlú Jaseri, gbogbo ìlú Gileadi àti ìdajì orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ ará Ammoni títí dé Aroeri, ní ẹ̀bá Rabba;
àti láti Heṣboni lọ sí Ramati-Mispa àti Betonimu, àti láti Mahanaimu sí agbègbè ìlú Debiri,
àti ní àfonífojì Beti-Haramu, Beti-Nimra, Sukkoti àti Safoni pẹ̀lú ìyókù agbègbè ilẹ̀ Sihoni ọba Heṣboni (ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani, agbègbè rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kinnereti).
Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé.
Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Manase, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú-ọmọ Manase, ní agbo ilé ní agbo ilé.
Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Mahanaimu àti gbogbo Baṣani, gbogbo agbègbè ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani, èyí tí í ṣe ibùgbé Jairi ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú,
ìdajì Gileadi, àti Aṣtarotu àti Edrei (àwọn ìlú ọba Ogu ní Baṣani). Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Makiri, ní agbo ilé ní agbo ilé.
Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko.