Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Slander

116 ẹsẹ · 71 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun; ó dàbí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.

  2. Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

  3. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún.

  4. nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn ti ya ẹnu wọn sí mi wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.

  5. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí

  6. Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá; àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

  7. Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

  8. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,

  9. ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.

  10. Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

  11. Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.

  12. Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.

  13. Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.

  14. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.

  15. Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn; wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

  16. Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

  17. Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

  18. Láìsí igi, iná yóò kú láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.

  19. Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

  20. Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

  21. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀; ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.

  22. Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.

  23. “Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ. Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.

  24. Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo. Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

  25. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ-ogun tókù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ìre fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”