Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Slander

116 ẹsẹ · 71 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ilédélé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ.

  2. Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá,

  3. Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ batẹnijẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.

  4. Rán àwọn ènìyàn náà létí láti máa tẹríba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ. Kí wọn ṣe ìgbọ́ràn nígbà gbogbo, kí wọn sì múra fún iṣẹ́ rere gbogbo.

  5. Wọn kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ní ibi, kí wọn jẹ́ ẹni àlàáfíà àti ẹni pẹ̀lẹ́, kí wọn sì máa fi ìwà tútù gbogbo hàn sí gbogbo ènìyàn.

  6. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán.

  7. Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́.

  8. Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?

  9. Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo.

  10. Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.

  11. Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

  12. Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi.

  13. Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.

  14. Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.

  15. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá.

  16. Mo sì gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run, wí pè: “Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá, àti ọlá àti Kristi rẹ̀. Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arákùnrin wa jáde, tí o ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn án àti lóru.