Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.

  2. Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.

  3. Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá.

  4. Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

  5. Ti Dafidi. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

  6. Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò, dán àyà àti ọkàn mi wò;

  7. nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

  8. Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.

  9. Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

  10. Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.

  11. Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́, èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

  12. Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.

  13. Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,

  14. àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

  15. Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́; rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

  16. Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

  17. Ti Dafidi. Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

  18. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

  19. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

  20. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

  21. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

  22. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

  23. Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Olúwa, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn,

  24. Ọkàn mi wí pé, “Wá ojú u rẹ̀!” Ojú rẹ, Olúwa, ni ti èmí ń wá.

  25. Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì; ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí, háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.