Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá, òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.

  2. Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀; kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

  3. Pípé ni òfin Olúwa, ó ń yí ọkàn padà. Ẹ̀rí Olúwa dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

  4. Ìlànà Olúwa tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ Olúwa ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

  5. Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ Olúwa dájú òdodo ni gbogbo wọn.

  6. Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ.

  7. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

  8. Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀? Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

  9. Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá; má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi. Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin, èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

  10. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

  11. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

  12. Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

  13. Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela.

  14. Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.

  15. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

  16. Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé, Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́. Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

  17. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

  18. Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.

  19. Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

  20. Ti Dafidi. Saamu. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

  21. nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

  22. Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

  23. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.

  24. Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

  25. Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.