Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Protection

128 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ; ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

  2. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,

  3. Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

  4. Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

  5. Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú.

  6. A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.

  7. Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.

  8. nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

  9. bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.

  10. Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin. Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

  11. Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

  12. Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

  13. Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ, n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

  14. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

  15. Ọkàn mí fà sí ọ: ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

  16. Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

  17. Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.

  18. Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

  19. Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  20. Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

  21. Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

  22. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

  23. tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

  24. Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

  25. Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.