Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Protection: Hosts

6 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Hosts

  1. Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun.

  2. Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ-ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Meromu láti bá Israẹli jà.

  3. Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

  4. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromu, wọ́n sì kọlù wọ́n,

  5. Olúwa sì fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sidoni ńlá, sí Misrefoti-Maimu, àti sí àfonífojì Mispa ní ìlà-oòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.

  6. A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.