Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Protection: Peter

4 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Peter

  1. Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́.

  2. Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.

  3. Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà.

  4. Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.