Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Protection: Idols

4 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Idols

  1. Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí, àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,

  2. ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn? Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n! Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!

  3. “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni! Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi. Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè. Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná, kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

  4. Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà. Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.