Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Praise

490 ẹsẹ · 106 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!

  2. Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

  3. Ẹ kọrin sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn sí i, ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù. Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

  4. Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.

  5. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́; àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.

  6. Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé, kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.

  7. Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.

  8. Kéde agbára Ọlọ́run, ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli, tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.

  9. Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

  10. Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,

  11. Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

  12. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.

  13. Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

  14. Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

  15. Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

  16. Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.

  17. Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.

  18. Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin. A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

  19. Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ, àti àgùntàn pápá rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.

  20. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu. Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!

  21. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ; wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

  22. Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.

  23. Maskili ti Etani ará Esra. Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé; pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

  24. Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.

  25. Olùbùkún ní Olúwa títí láé.