Skip to content

Olives

11 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Olivet

31.7700, 35.2400 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Olives

  1. Dafidi sì ń gòkè lọ ní òkè igi olifi, o sì ń sọkún bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹsẹ̀, gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ.

  2. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àfonífojì ńlá ńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù.

  3. Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì,

  4. Bí ó ti jókòó ní orí òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wọ́n wí pé, “Sọ fún wa nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ àmì ìpadà wá rẹ, àti ti òpin ayé?”

  5. Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Olifi.

  6. Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú.

  7. Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé,

  8. Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè olifi lọ.

  9. Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí,

  10. Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  11. Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.