Skip to content

Andrew

12 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Andrew

  1. Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n.

  2. Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

  3. Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n.

  4. Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu.

  5. Àti Anderu, Filipi, Bartolomeu, Matiu, Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Taddeu, Simoni tí ń jẹ́ Sealoti

  6. Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé,

  7. Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀, Jakọbu, Johanu, Filipi, Bartolomeu,

  8. Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn.

  9. Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida.

  10. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Anderu, arákùnrin Simoni Peteru wí fún un pé,

  11. Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu.

  12. Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni: Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu; Filipi àti Tomasi; Bartolomeu àti Matiu; Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu.