- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Apostles
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n.
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”
Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú.
Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́.
Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”
Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Ó sì ṣe, bí Jesu tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Matiu, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.
Filipi àti Bartolomeu; Tomasi àti Matiu agbowó òde; Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;
Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.
Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?
Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsin yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìṣù àkàrà márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kójọ bí àjẹkù?
Ẹ kò sì tún rántí ìṣù méje tí mo fi bọ́ ẹgbàajì (4,000) ènìyàn àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yín kójọ?
Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.”
Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi.
Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.
Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀.
Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”
Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.
Peteru mú Jesu sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa! Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ!”
Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.
Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”