Skip to content

James

18 ẹsẹ · 3 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Boanerges

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan James

  1. Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú.

  2. Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

  3. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró.

  4. Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.

  5. Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu.

  6. Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí “àwọn ọmọ àrá”).

  7. Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu.

  8. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn.

  9. Lẹ́yìn èyí, Jakọbu àti Johanu, àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.”

  10. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú.

  11. Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé,

  12. Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi.

  13. bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni. Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.”

  14. Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀, Jakọbu, Johanu, Filipi, Bartolomeu,

  15. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà.

  16. Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.

  17. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?”

  18. Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu.