Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Eucharist

44 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”

  2. Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé, àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”

  3. Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.

  4. Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jesu ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá,

  5. nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”

  6. Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”

  7. Jesu dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn.

  8. Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”

  9. Judasi, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Rabbi, èmi ni bí?” Jesu sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i.”

  10. Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”

  11. Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀.

  12. Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  13. Sì kíyèsi àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”

  14. Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Olifi.

  15. Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”

  16. Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.

  17. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

  18. Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

  19. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.

  20. Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.

  21. Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;

  22. tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run;

  23. Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè.

  24. Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.

  25. Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.