Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Praise

490 ẹsẹ · 106 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá; ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀

  2. Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.

  3. Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.

  4. Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá.

  5. Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

  6. Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

  7. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

  8. Alábùkún fún ni Olúwa! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

  9. Olúwa ni agbára mi àti asà mi; nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

  10. Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  11. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo; ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

  12. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo; ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.

  13. Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.

  14. Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.

  15. Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

  16. Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa; jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

  17. Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

  18. Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá; èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  19. Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

  20. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

  21. Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.

  22. Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  23. Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé.

  24. Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi: èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

  25. Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi? Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi? Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín, Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.