Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parents

156 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.

  2. Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.

  3. Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìsàlẹ̀.

  4. Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.

  5. Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”

  6. Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.”

  7. Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi.

  8. Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.

  9. Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao.

  10. Èmi sì yàn án kúrò láàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rú ẹbọ lórí pẹpẹ mi, láti fi tùràrí jóná, láti wọ efodu níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Israẹli máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀.

  11. Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo pàṣẹ ní ibùjókòó mi, ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jù mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Israẹli àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’

  12. “Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.

  13. Kíyèsi i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ.

  14. Ìwọ yóò rí wàhálà ti Àgọ́, nínú gbogbo ọlá tí Ọlọ́run yóò fi fún Israẹli; kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láéláé.

  15. Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ní ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sọkún yọ lójú àti láti banújẹ́. Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

  16. “ ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, yóò jẹ́ àmì fún ọ—àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà.

  17. Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi, ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi. Èmi yóò fi ẹsẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo.

  18. Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”

  19. Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.

  20. Nígbà náà àwọn Filistini jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Israẹli olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn ará Israẹli tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọmọ-ogun orí ilẹ̀.

  21. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Olúwa, àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì sì kú, Hofini àti Finehasi.

  22. Lọ́jọ́ kan náà tí ará Benjamini kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣilo, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀.

  23. Nígbà tí ó sì dé, Eli sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

  24. Eli gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ ariwo yìí?” Ọkùnrin náà sì sáré tọ Eli wá

  25. Eli sì di ẹni méjìdínlọ́gọ́run (98) ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́.