Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parents: Curses entailed

7 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Curses entailed

  1. Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.

  2. Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ké wọn kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn, òun àti gbogbo àwọn tí ó jọ ṣe àgbèrè tọ òrìṣà Moleki lẹ́yìn.

  3. a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ. Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.

  4. Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.

  5. Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  6. “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.”

  7. Ìwọ ni ọmọ ìyá rẹ ti ó kọ ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀; ìwọ ni arábìnrin àwọn arábìnrin rẹ tí ó kọ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn: ara Hiti ni ìyá rẹ, ara Amori sì ni baba rẹ.