Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parents: Paternal reproaches

7 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Paternal reproaches

  1. Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i.

  2. Ó wí pé, “Ègún ni fún Kenaani. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

  3. “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi, títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.

  4. Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀).

  5. “Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin— idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.

  6. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.

  7. Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà! Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli.