Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parents

156 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọkùnrin náà sọ fún Eli, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi ogun náà ni: mo sá láti ibi ogun náà wá lónìí.” Eli sì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ọmọ mi?”

  2. Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn Filistini, ìṣubú àwọn ọmọ-ogun náà sì pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ.”

  3. Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa, Eli sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Israẹli fún ogójì ọdún.

  4. Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Finehasi, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà.

  5. Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i.

  6. Ó sì pe ọmọ náà ní Ikabodu, wí pé, “Kò sí ògo fún Israẹli mọ́,” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀.

  7. Ó si wí pé, “Ògo kò sí fún Israẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run.”

  8. Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni.

  9. Dafidi sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dafidi sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lórí ilé ni òru náà.

  10. Ọba sì pàṣẹ fún Joabu àti Abiṣai àti Ittai pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Absalomu.

  11. Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Absalomu! Ọmọ mi, ọmọ mí Absalomu! Á à! Ìbá ṣe pé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”

  12. “Orí mi! Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀. Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.”

  13. Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú.

  14. “Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé.

  15. Àti fún ọmọ mi Solomoni ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

  16. Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú.

  17. Ó sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ kí ó kọjá láàrín iná ní àfonífojì Beni-Hinnomu, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

  18. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.

  19. Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.

  20. Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀.

  21. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

  22. nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn.

  23. Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

  24. Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,

  25. Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé: ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.