Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offerings

433 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.)

  2. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.

  3. Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

  4. Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbọdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsin yìí, ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

  5. Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.

  6. Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà.

  7. Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún (1,000) kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin (1,000) kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli.

  8. Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun. Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ilé Olúwa.

  9. Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí.

  10. Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀.

  11. Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu.

  12. “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.

  13. “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.

  14. Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn.

  15. Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.

  16. Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí.

  17. Mo sì tún pèsè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so. Rántí mi fún rere, Ọlọ́run mi.

  18. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

  19. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè.

  20. Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé.

  21. Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

  22. Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ rẹ, tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo.

  23. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un, tàbí kí o mú òbúkọ láti inú agbo ẹran rẹ̀

  24. nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún (1,000) òkè.

  25. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.