Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Offerings

433 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná.

  2. Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún.

  3. Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  4. Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu.

  5. Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

  6. “ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

  7. Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa.

  8. Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan.

  9. Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá.

  10. Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín.

  11. Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.

  12. Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.

  13. “ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

  14. Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín.

  15. Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ọrẹ ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òsùwọ̀n fún àgbò kan,

  16. àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n.

  17. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.

  18. Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

  19. Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  20. “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù.

  21. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

  22. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.

  23. “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù.

  24. Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

  25. Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.