Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings

580 ẹsẹ · 175 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.

  2. Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu.

  3. Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.

  4. Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú Olúwa fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe.

  5. Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Babeli tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdébìnrin, wúńdíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadnessari lọ́wọ́.

  6. Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Babeli, ńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀.

  7. Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́.

  8. Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára.

  9. Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremiah.

  10. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda.

  11. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu.

  12. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

  13. Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní Babeli.

  14. A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Ìwé ìrántí.

  15. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu. Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà,

  16. pẹ̀lú ipele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.

  17. Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadnessari kó láti ilé Olúwa ní Jerusalẹmu tí ó sì kó lọ sí Babeli, di dídápadà sí ààyè wọn nínú tẹmpili ní Jerusalẹmu; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.

  18. Nítorí náà, kí ìwọ, Tatenai baálẹ̀ agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà kúrò níbẹ̀.

  19. Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì dí i lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbàgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.

  20. Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí. Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró.

  21. Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀.

  22. Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀.

  23. Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.

  24. Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní Jerusalẹmu run. Èmi Dariusi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà.

  25. Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n; ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.