Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings: Rehoboam (latter part of his reign)

15 ẹsẹ · 175 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Rehoboam (latter part of his reign)

  1. Nígbà tí Rehoboamu sì dé sí Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ilé Juda jọ, àti ẹ̀yà Benjamini; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Israẹli jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.

  2. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé,

  3. “Sọ fún Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda àti fún gbogbo ilé Juda àti ti Benjamini, àti fún àwọn ènìyàn tókù wí pé,

  4. ‘Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Israẹli. Kì olúkúlùkù yín padà sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.” ’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

  5. Rehoboamu ọmọ Solomoni sì jẹ ọba ní Juda. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jerusalẹmu, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama, ará Ammoni.

  6. Juda sì ṣe búburú níwájú Olúwa nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ.

  7. Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère òkúta àti òpó Aṣerah lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

  8. Àwọn tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà wà ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

  9. Ó sì ṣe ní ọdún karùn-ún Rehoboamu, Ṣiṣaki ọba Ejibiti kọlu Jerusalẹmu.

  10. Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú asà wúrà tí Solomoni ti ṣe.

  11. Rehoboamu ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlẹ̀kùn ilé ọba.

  12. Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa, wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.

  13. Ní ti ìyókù ìṣe Rehoboamu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda bí?

  14. Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní ọjọ́ wọn gbogbo.

  15. Rehoboamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú Dafidi. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama; ará Ammoni. Abijah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.