Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings: Jehoiakim

4 ẹsẹ · 175 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Jehoiakim

  1. Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

  2. Nebukadnessari ọba Babeli sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú un lọ sí Babeli.

  3. Nebukadnessari kó nínú ohun èlò ilé Olúwa lọ si Babeli pẹ̀lú, ó sì fi wọn sí ààfin rẹ̀ ní Babeli.

  4. Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.