Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings: Sin of Israel in seeking

4 ẹsẹ · 175 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Sin of Israel in seeking

  1. Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”

  2. Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.

  3. Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”

  4. Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa.