- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Wọn si wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi púpọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Israẹli.”
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógun sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn.
Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lú orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbèkùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jeriko, ìlú ọ̀pẹ, wọ́n sì padà sí Samaria.
Ní àkókò ìgbà náà, ọba Ahasi ránṣẹ́ sí ọba Asiria fún ìrànlọ́wọ́.
Àwọn ará Edomu sì tún padà wá láti kọlu Juda kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ.
Nígbà tí àwọn ará Filistini sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n nì àti síhà gúúsù Juda. Wọ́n ṣẹ́gun wọ́n sì gba Beti-Ṣemeṣi, Aijaloni àti Gederoti, àti Soko, Timna, a ri Gimiso, pẹ̀lú ìletò wọn.
Olúwa sì rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi ọba Israẹli, nítorí ó sọ Juda di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì ṣe ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.
Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.
Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa.
Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Damasku, ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn ọba Siria ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Israẹli.
Ahasi sì kó gbogbo ohun èlò láti ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jerusalẹmu.
Ní gbogbo ìlú Juda ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn bínú.
Ìyókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Juda àti ti Israẹli.
Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jerusalẹmu ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn isà òkú àwọn ọba Israẹli. Hesekiah ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Manase jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta.
Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli rìn.
Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Baali ó sì ṣe àwọn ère Aṣerah. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n.
Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé Olúwa ní èyí tí Olúwa ti wí pé, “Orúkọ mi yóò wà ní Jerusalẹmu títí láé.”
Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run
Ó sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ kí ó kọjá láàrín iná ní àfonífojì Beni-Hinnomu, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.
Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.
Èmi kì yóò ṣí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli kúrò mọ́ ní ilẹ̀ náà tí èmi ti yàn fún àwọn baba ńlá yín, níwọ̀n bí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin, àṣẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín láti ọwọ́ Mose wá.”
Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
Olúwa bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i.