Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Christ is God

56 ẹsẹ · 55 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run

  2. Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá Olúwa ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,

  3. àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀.

  4. Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́. Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè, kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”

  5. Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”

  6. Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?”

  7. Ki ni ẹ ti rò èyí sí. Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”

  8. Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú.

  9. Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú, láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”

  10. Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”

  11. Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba. Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’

  12. Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

  13. Nítorí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.”

  14. Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e.

  15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

  16. Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni.

  17. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi.

  18. Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.

  19. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.

  20. Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí.

  21. Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù.

  22. Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.

  23. Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ.

  24. Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀.

  25. Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.