Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Christ is God: As the Eternal God and Creator

7 ẹsẹ · 55 abala

Àwọn ẹsẹ nípa As the Eternal God and Creator

  1. Èmi sì wí pé: “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.

  2. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  3. Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì.

  4. Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀, ọdún rẹ kò sì ní òpin.

  5. Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.

  6. Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.

  7. Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ, bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ̀ kì yóò yípadà àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”