Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 9:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.

  2. Deuteronomi 9:24nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa.

  3. Deuteronomi 9:25nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run.

  4. Deuteronomi 9:26nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti rà padà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Ejibiti wá.

  5. Deuteronomi 9:27nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  6. Deuteronomi 9:28nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, ‘Torí pé Olúwa kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní aginjù.’

  7. Deuteronomi 9:29nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde.”

  8. Deuteronomi 10:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan.

  9. Deuteronomi 10:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”

  10. Deuteronomi 10:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí.

  11. Deuteronomi 10:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí wàláà wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi.

  12. Deuteronomi 10:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn wàláà òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.

  13. Deuteronomi 10:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    (Àwọn ará Israẹli sì gbéra láti kànga àwọn ará Jaakani dé Mosera. Níbí ni Aaroni kú sí, tí a sì sin ín, Eleasari ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.

  14. Deuteronomi 10:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gudgoda, títí dé Jotbata, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn.

  15. Deuteronomi 10:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà yìí ni Olúwa yan àwọn ẹ̀yà Lefi láti máa ru àpótí ẹ̀rí Olúwa, láti máa dúró níwájú Olúwa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ Olúwa súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.

  16. Deuteronomi 10:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrín àwọn arákùnrin wọn. Olúwa ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)

  17. Deuteronomi 10:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín.

  18. Deuteronomi 10:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”

  19. Deuteronomi 10:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ,

  20. Deuteronomi 10:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.

  21. Deuteronomi 10:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

  22. Deuteronomi 10:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní.

  23. Deuteronomi 10:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ.

  24. Deuteronomi 10:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

  25. Deuteronomi 10:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.