- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Deuteronomi 11:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ẹ bá fi ara balẹ̀ kíyèsi àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé, láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìímú ṣinṣin:
- Deuteronomi 11:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.
- Deuteronomi 11:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aginjù dé Lebanoni, àti láti odò Eufurate dé Òkun Ńlá.
- Deuteronomi 11:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.
- Deuteronomi 11:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí:
- Deuteronomi 11:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
- Deuteronomi 11:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.
- Deuteronomi 11:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ebali.
- Deuteronomi 11:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jordani ní apá ìwọ̀-oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó More, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbègbè Gilgali.
- Deuteronomi 11:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹ ti ṣetán láti la Jordani kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀,
- Deuteronomi 11:32nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.
- Deuteronomi 12:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra láti máa tẹ̀lé, ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, fi fún un yín láti gbà: ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ náà.
- Deuteronomi 12:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátápátá.
- Deuteronomi 12:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, ẹ bi òpó ìsìn wọn ṣubú, kí ẹ sì sun òpó Aṣerah wọn ní iná. Ẹ gé gbogbo ère òrìṣà wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ ní gbogbo ààyè wọn.
- Deuteronomi 12:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí i tiwọn.
- Deuteronomi 12:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà yín, láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ.
- Deuteronomi 12:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín.
- Deuteronomi 12:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.
- Deuteronomi 12:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí a tí ṣe níhìn-ín lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀.
- Deuteronomi 12:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Níwọ́n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.
- Deuteronomi 12:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jordani kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrín àwọn ọ̀tá a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ ba à lè máa gbé láìléwu.
- Deuteronomi 12:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa.
- Deuteronomi 12:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́bìnrin àti ìránṣẹ́kùnrin yín, àti àwọn Lefi láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.
- Deuteronomi 12:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ sísun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́.
- Deuteronomi 12:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa kíyèsi ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.