circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Marku 1:30nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀.
- Marku 1:31nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
- Marku 1:32nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá.
- Marku 1:33nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà.
- Marku 1:34nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
- Marku 1:35nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà.
- Marku 1:36nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.
- Marku 1:37nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
- Marku 1:38nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”
- Marku 1:39nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
- Marku 1:40nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”
- Marku 1:41nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”
- Marku 1:42nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
- Marku 1:43nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi
- Marku 1:44nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.”
- Marku 1:45nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.
- Marku 2:1nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé.
- Marku 2:2nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn.
- Marku 2:3nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé.
- Marku 2:4nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.
- Marku 2:5nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
- Marku 2:6nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,
- Marku 2:7nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
“Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”
- Marku 2:8nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?
- Marku 2:9nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?’