circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Marku 2:10nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé,
- Marku 2:11nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
“Mo wí fún ọ, dìde, gbé àkéte rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.”
- Marku 2:12nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”
- Marku 2:13nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà, Jesu tún jáde lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn.
- Marku 2:14nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Bí ó ti ń rin etí Òkun lọ sókè, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,” Lefi dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.
- Marku 2:15nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e.
- Marku 2:16nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èétirí tí ó fi ń bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
- Marku 2:17nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
- Marku 2:18nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀. Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”
- Marku 2:19nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò ṣe máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó ṣì wà lọ́dọ̀ wọn?
- Marku 2:20nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.”
- Marku 2:21nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
“Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, bí ó ba ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tuntun tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fàya kúrò lára ògbólógbòó, yíya rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù.
- Marku 2:22nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a sì dàànù, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”
- Marku 2:23nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà.
- Marku 2:24nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”
- Marku 2:25nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?
- Marku 2:26nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Abiatari olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ àkàrà ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
- Marku 2:27nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi.
- Marku 2:28nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú.”
- Marku 3:1nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.
- Marku 3:2nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu. Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi.
- Marku 3:3nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”
- Marku 3:4nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
- Marku 3:5nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.
- Marku 3:6nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu.