Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 33:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    nínú ìjà pẹ̀lú Kaldea: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn.

  2. Jeremiah 33:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.

  3. Jeremiah 33:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀.

  4. Jeremiah 33:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n.

  5. Jeremiah 33:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’

  6. Jeremiah 33:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí.

  7. Jeremiah 33:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé: “ ‘ “Yin Olúwa àwọn ọmọ-ogun, nítorí Olúwa dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.” Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni Olúwa wí.

  8. Jeremiah 33:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi.

  9. Jeremiah 33:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

  10. Jeremiah 33:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ.

  11. Jeremiah 33:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi. Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

  12. Jeremiah 33:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà. Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu. Orúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’

  13. Jeremiah 33:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli.

  14. Jeremiah 33:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”

  15. Jeremiah 33:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá wí pé:

  16. Jeremiah 33:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́.

  17. Jeremiah 33:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dafidi ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dafidi kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

  18. Jeremiah 33:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Èmi ó mú àwọn ọmọ lẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ”

  19. Jeremiah 33:23nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:

  20. Jeremiah 33:24nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsi pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan.

  21. Jeremiah 33:25nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀.

  22. Jeremiah 33:26nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọ lẹ́yìn Jakọbu àti Dafidi ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn ọmọ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”

  23. Jeremiah 34:1nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ọba tí ó jẹ ọba lé lórí ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yíká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé:

  24. Jeremiah 34:2nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ọmọ-ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekiah ọba Juda kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa ìlú yìí lé ọba Babeli lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀.

  25. Jeremiah 34:3nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí ọba Babeli pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Babeli.