circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 32:24nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe kórajọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kaldea tí ń gbóguntì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i.
- Jeremiah 32:25nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀ a ó fi ìlú náà fún àwọn ará Babeli, ìwọ Olúwa Olódùmarè sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”
- Jeremiah 32:26nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá pé:
- Jeremiah 32:27nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí?
- Jeremiah 32:28nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí, Èmi ṣetán láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kaldea àti fún Nebukadnessari ọba Babeli ẹni tí yóò kó o.
- Jeremiah 32:29nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Àwọn ará Kaldea tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ pẹ̀lú ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rú ẹbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Baali tiwọn sì ń da ẹbọ ohun mímu fún àwọn ọlọ́run mìíràn.
- Jeremiah 32:30nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Àwọn ènìyàn Israẹli àti Juda kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí.
- Jeremiah 32:31nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi.
- Jeremiah 32:32nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu.
- Jeremiah 32:33nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Wọ́n kọ ẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbi ara sí ìwà ìbàjẹ́.
- Jeremiah 32:34nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ṣọ́ di àìmọ́.
- Jeremiah 32:35nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Baali ní àfonífojì Hinnomu láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rú ẹbọ sí Moleki. Èmi kò pàṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Juda dẹ́ṣẹ̀.
- Jeremiah 32:36nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn ni à ó fi wọ́n fún ọba Babeli,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ nìyìí,
- Jeremiah 32:37nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu.
- Jeremiah 32:38nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
- Jeremiah 32:39nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn.
- Jeremiah 32:40nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn, Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi.
- Jeremiah 32:41nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Lóòtítọ́, èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbígbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.
- Jeremiah 32:42nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Nítorí báyìí ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa tiwọn wá sórí wọn.
- Jeremiah 32:43nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Lẹ́ẹ̀kan sí i, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, ‘Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará Babeli.’
- Jeremiah 32:44nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Benjamini àti ní ìlú kéékèèké tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda àti ní ìlú àwọn ìlú orí òkè, àti ni àwọn ẹsẹ̀ òkè, àti ní gúúsù, èmi ó mú ìgbèkùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”
- Jeremiah 33:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì:
- Jeremiah 33:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹni tí ó dá ayé, Olúwa tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, Olúwa ni orúkọ rẹ̀:
- Jeremiah 33:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’
- Jeremiah 33:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn ọba Juda tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà