Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 31:14nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀; àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,” ni Olúwa wí.

  2. Jeremiah 31:15nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “A gbọ́ ohùn kan ní Rama tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò. Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀; kò gbà kí wọ́n tu òun nínú, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

  3. Jeremiah 31:16nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa wí: “Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún àti ojú rẹ nínú omijé; nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.

  4. Jeremiah 31:17nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,” ni Olúwa wí. “Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.

  5. Jeremiah 31:18nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé, ‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́ èmi sì ti gbọ́ ìbáwí. Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà, nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.

  6. Jeremiah 31:19nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà, mo ronúpìwàdà, lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀, èmi lu àyà mi. Ojú tì mí, mo sì dààmú; nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’

  7. Jeremiah 31:20nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni Olúwa wí.

  8. Jeremiah 31:21nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde, ṣe atọ́nà àmì, kíyèsi òpópó ọ̀nà geere ojú ọ̀nà tí ó ń gbà. Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli, padà sí àwọn ìlú rẹ.

  9. Jeremiah 31:22nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin; Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀, ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”

  10. Jeremiah 31:23nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí Olúwa kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’

  11. Jeremiah 31:24nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká.

  12. Jeremiah 31:25nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.”

  13. Jeremiah 31:26nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

  14. Jeremiah 31:27nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.

  15. Jeremiah 31:28nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí.

  16. Jeremiah 31:29nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé: “ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’

  17. Jeremiah 31:30nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan.

  18. Jeremiah 31:31nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.

  19. Jeremiah 31:32nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi. Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,” ni Olúwa wí.

  20. Jeremiah 31:33nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.

  21. Jeremiah 31:34nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni Olúwa wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

  22. Jeremiah 31:35nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

  23. Jeremiah 31:36nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.”

  24. Jeremiah 31:37nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀, ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,” ni Olúwa wí.

  25. Jeremiah 31:38nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè.