Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 29:20nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

  2. Jeremiah 29:21nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.

  3. Jeremiah 29:22nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Olúwa yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’

  4. Jeremiah 29:23nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Israẹli, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí Èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí.

  5. Jeremiah 29:24nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Wí fún Ṣemaiah tí í ṣe Nehalami pé,

  6. Jeremiah 29:25nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu sí Sefaniah ọmọ Maaseiah tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefaniah wí pé,

  7. Jeremiah 29:26nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    ‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.

  8. Jeremiah 29:27nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremiah ará Anatoti wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrín yín?

  9. Jeremiah 29:28nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Babeli wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

  10. Jeremiah 29:29nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Sefaniah àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jeremiah tí í ṣe wòlíì.

  11. Jeremiah 29:30nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé,

  12. Jeremiah 29:31nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    “Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn ìgbèkùn wí pé: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí ní ti Ṣemaiah, ará Nehalami: Nítorí pé Ṣemaiah ti sọtẹ́lẹ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké.

  13. Jeremiah 29:32nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Wò ó, èmi yóò bẹ Ṣemaiah, ará Nehalami wò, àti irú-ọmọ rẹ̀; òun kì yóò ní ọkùnrin kan láti máa gbé àárín ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí rere náà tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi ni Olúwa wí, nítorí ó ti ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi.’ ”

  14. Jeremiah 30:1nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé:

  15. Jeremiah 30:2nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan.

  16. Jeremiah 30:3nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”

  17. Jeremiah 30:4nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda:

  18. Jeremiah 30:5nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́ láìṣe igbe àlàáfíà.

  19. Jeremiah 30:6nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Béèrè kí o sì rí. Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?

  20. Jeremiah 30:7nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.

  21. Jeremiah 30:8nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.

  22. Jeremiah 30:9nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.

  23. Jeremiah 30:10nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.

  24. Jeremiah 30:11nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá. Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan; Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’

  25. Jeremiah 30:12nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.