circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 28:12nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé:
- Jeremiah 28:13nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
“Lọ sọ fún Hananiah, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní ààyè wọn, wà á bá àjàgà onírin.
- Jeremiah 28:14nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè láti lè máa sin Nebukadnessari ọba Babeli, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Èmi yóò tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”
- Jeremiah 28:15nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! Olúwa kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́.
- Jeremiah 28:16nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ”
- Jeremiah 28:17nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi
Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananiah wòlíì kú.
- Jeremiah 29:1nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremiah rán láti Jerusalẹmu sí ìyókù nínú àwọn àgbàgbà tí ó wà ní ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari tí kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.
- Jeremiah 29:2nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí Jekoniah, ọba, àti ayaba, àti àwọn ìwẹ̀fà, àti àwọn ìjòyè Juda àti Jerusalẹmu, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu.
- Jeremiah 29:3nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Ó fi lẹ́tà náà rán Eleasa ọmọ Ṣafani àti Gemariah ọmọ Hilkiah, ẹni tí Sedekiah ọba Juda rán sí Nebukadnessari ọba Babeli. Wí pé.
- Jeremiah 29:4nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu ní Babeli:
- Jeremiah 29:5nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
“Ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín.
- Jeremiah 29:6nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ sí i ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá.
- Jeremiah 29:7nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”
- Jeremiah 29:8nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárín yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá.
- Jeremiah 29:9nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi, Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 29:10nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu.
- Jeremiah 29:11nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú.
- Jeremiah 29:12nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.
- Jeremiah 29:13nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí.
- Jeremiah 29:14nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Èmi yóò di rí rí fún yín ni Olúwa wí, Èmi yóò sì mú yín padà kúrò ní ìgbèkùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ibi gbogbo tí Èmi ti lé yín jáde, ni Olúwa wí. Èmi yóò sì kó yín padà sí ibi tí mo ti mú kí a kó yín ní ìgbèkùn lọ.”
- Jeremiah 29:15nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin lè wí pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Babeli.”
- Jeremiah 29:16nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi àti ní ti gbogbo ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú yìí; àní ní ti àwọn ènìyàn yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn,
- Jeremiah 29:17nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
bẹ́ẹ̀ ni, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín wọn; Èmi yóò ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ.
- Jeremiah 29:18nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí.
- Jeremiah 29:19nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi
Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí.